Abridged Pathways
A poem about the life of David Olúwálé Abíọ́dún Abdul self-translated from Yorùbá by the poet Èkó hometown baby, echoing my namesake Olúwálé: ‘the Lord has come home’, sanctified child ‘Beloved’ David anointed with divine promise Hull-bound hull stowaway, blessed waters taking me further Riding floating ‘Temples’ to new life adventures On British shores with Atlantic cousins My tailor-made talents leading to Leeds Bold colour appreciates fabrics…yet depreciates skin? What exclusive madness is their blurred vision?? Now truncating my senses through truncheon hallucinations Granted asylum from Menston Asylum Jobless, homeless: divinity on the margins Rough-sleeping voyager staying in my lanes Huh? Police peacekeepers harass my peace, why? Asylum revoked, drugged-up electric shocks, blurred echo/Èkó The Lord has come home…to hellish streets Shielded demons war my celestial being Groin kicks, piss takes, acid-spitting racist edicts, Prostrating pavement headbutt ‘penance’ For what offence except melanated virtue? Badged monsters badger Aire into my lungs Murky waters muffle witness voices and whitewash crimes Diluted justice sends me on heavenly tides, Though righteous resistance ripples forever forward My divine promise bridging hopeful pathways home |
Ọ̀nà Kúkúrú
Ewì nípa ayé Dáfídì Olúwálé Abíọ́dún Abdul Gẹ́gẹ́bí àròbó bíbí Ilú-Èkó, ìró ohùn idi orukọ mi Olúwálé: ‘Olúwa-ti-dé-ilé’, ọmọ tí a yà sí mímọ́ ‘Olùfẹ́’ Dáfídì ti a fi ìlérí àtọrunwá yàn Fifara pamọ si ọkọ̀ òkun to ń da ri si Ilú-Hull, omi ìbùkún to ń mu mi lọ síwájú Gígùn ‘Ile Ọlọrun’ lílèfoo si ìrìn ayé tuntun L’orí àwọn etí òkun Gẹ̀ẹ́sì pẹ̀lú ìbátan Atilantiki Ẹ̀bùn ìránṣọ mi yori si Ilú-Leeds Àwọ̀ to yọjú mọyì aṣọ… sibẹsibẹ ó rẹ awọ-ará sílẹ̀? Kíni ásínwín pẹ̀lú ìyàsọtọ àti bàì-bàì ìríran wọn?? Bayi, gẹ́gẹ́ ọgbọ́n orí mi kúrú bẹ̀rẹ̀ nípasẹ̀ irokuro gbóńgbó ọ̀lọ́pàá Ìtúsílẹ̀ kúrò ni Àtìmọ́lé Menston Mi ò ní iṣẹ́, mi ò ní ilé gbé: mímọ́ lorí ẹ̀gbẹ̀ Arìnrìn-àjò tí ń sùn ní inira díduro ní ọ̀nà tooro mi Aa? Ọ̀lọ́pàá olúṣọ ìfọkànbalẹ̀ to ń yọ ìfọkànbalẹ̀ mi lẹnu, kílódé? Ìfagilée ipò, itanná mọ̀nàmọ́ná pẹ̀lú egbòògi olóró, bàì-bàì ìró ohùn/Ilú-Èkó Olúwa-ti-dé-ilé… si òpópónà àpáàdí Àlújọnú burúkú pẹ̀lú aabo ogun ọrún ará-ẹni mi Tààpá si l'abẹ́, ìtọ̀ gbá, títutọ́-omiró aṣẹ ìṣẹlẹ́yàmẹ̀yà Ìdọ̀bálẹ̀ pepele ìgbò ‘ìjìyà’ Fún ẹ̀ṣẹ̀ wo àyàfi ìwà-rere adúmáradán? Àwọn Ewèlè pẹ̀lú àmì ìdánimọ̀ tií (Odò) Aire sinú ẹ̀dọ̀fóró mi Omi ẹrọ̀fọ̀ dákẹ́ ohùn ẹlẹ́rìí àti fọ ìwà-ọ̀daràn funfun Ìdájọ́ darú-dàpọ̀ ràn mí lọsí iji-ómi ọ̀run, Ṣùgbọ́n àtakò olódodo tàn kálẹ̀ síwájú títí láí-láí Ìlérí àtọrunwá mi ń so afárá ọ̀nà ìrètí sí ilé |